Isowolo-Ede Ofo ninu Asayan Oro ati Afo Yoruba
No Thumbnail Available
Date
2018
Authors
Journal Title
Journal ISSN
Volume Title
Publisher
Faculty of Arts, University of Ilorin
Abstract
Àmúlò oríṣìíríṣìí àwọn àbùdá ajẹmédè pè fún ìkẹ́sẹjárí, ìpegedé àti ìjágaara àmújáde ìtumọ̀ afọ̀ fún onímọ̀-èdè, nínú ìmọ̀ ìmédèlò. Ṣaájú àkókò yìí, kò tí ì sí iṣẹ́ ìwádìí kan gúnmọ́ lórí àtẹ tó ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí àwọn ìlànà ìṣowọ́lò-èdè ìṣọfọ̀ wọ̀nyìí ń kó láwùjọ Yorùbá. À̀làfo yìí niṣẹ́ ìwádìí yìí yóò dí. Nipasẹ̀ èyí, àtubọ̀tán iṣẹ́ yìí ni láti ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí ìlò ohùn àti ìró ẹ̀ka-èdè àti èdè àmúlò ń kó nínú ìmèdè bí atọ́ka ìṣọwọ́ afọ̀ fún ìkẹ́sẹjárí-ìlò-èdè àti àgbọ́yé-afọ̀ láwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ yìí ṣàmúlò èdè fáyẹ̀wò láti ara ìsọ̀rí ọfọ̀ látinú oríṣìí afọ̀. Ìtúpalẹ̀ àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò inú iṣẹ́ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ipa tí ìmọ̀ nípa ìlò ohùn àti ìró, èdè-àmúlò àti ẹ̀ka-èdè, bí atọ́ka ìṣọwọ́ afọ̀ ń kó nínú ìmèdè, ìkẹ́sẹjárí-ìlò-èdè, àgbọ́yé-afọ̀ àti ìtumọ̀ kò ṣe é fojú tín-ín-rín rárá. Èyí ni pé, láìsí ìpegedé àti ìjáfáfá aṣafọ̀ nínú ìṣafọ̀ àmúlò àwọn fọ́nrán-èdè fáyẹ̀wò tíṣẹ́ yìí fi ṣàtẹ̀gùn ìtúpalẹ̀, àìgbọ́ra-ẹni-yé, ìtumọ̀-òdì tàbí ìyítumọ̀po ni yóò wáyé nínú ìṣọfọ̀.
Description
Keywords
Ìṣọwọ́lò-èdè, Ìṣọwọ́, Ìró àti ohùn, Èdè-àmúlò, Ẹ̀ka-èdè, Ọfọ̀