Ifaara lori ise iwadii

No Thumbnail Available

Date

2016

Journal Title

Journal ISSN

Volume Title

Publisher

Department of Linguistics and Nigerian Languages

Abstract

Àwùjọ kan kò lè tẹ̀síwájú tí ó bá dúró ṣigidi sójú kan bíi adágún odò, àwùjọ tí kò bá sì fẹ́ bí ó tí wà ní ìbẹ̀rẹ̀ pẹ̀pẹ̀, dandan ni kí ó máa ṣán ọ̀nà bí àwùjọ náà yóò ṣe máa gbèrú. Ọ̀nà kan gbòógi láti ṣe èyí ni ṣíṣe iṣẹ́ ìwádìí lórí ìṣẹ̀lẹ̀, ìwà, ìṣe tàbí àṣà kan. Ó ṣòro gan an ni láti sọ oríkì iṣẹ́ ìwádìí ní pàtó. Ohun tí ó fa sábàbí ni pé oríṣìíríṣìí nǹkan tí ó ń lọ láwùjọ ẹ̀dá ni ìwádìí lè jẹmọ́. Èyí ló ká ni lọ́wọ́ kò láti ki iṣẹ́ ìwádìí ní oríkì gúnmọ́ kan. Iṣẹ́ ìwádìí lè jẹmọ́ wíwá ẹ̀rí kan gbòógì tí yóò ṣèrànwọ́ fún àwọn aláṣẹ lẹ́nu iṣẹ́, pàápàá èyí tó jẹ mọ́ ìgbésí ayé ẹ̀dá láwùjọ. Iṣẹ́ ìwádìí sì lè jẹ́ ọ̀nà láti ṣe ọ̀fíntótó lórí àtubọ̀tán tí ó le fara hàn lórí àjọṣepọ̀ láààrin ẹ̀dá méjì tàbí jù bẹ́ẹ̀ lọ. Nígbà tí a bá ń dọ̀rọ̀ rò lórí kókó ọ̀rọ̀, nǹkan tí a lè sọ ni pé iṣẹ́ ìwádìí ń tọ́ka sí àwọn àbùdá aṣàfihàn ẹ̀dá àwùjọ, àyíká àwùjọ́ ẹ̀dá, ìṣe, ìwà àti èrò àwọn ẹgbẹ́ tàbí ọgbà láwùjọ.

Description

Keywords

ki ni iwadii, abuda iwadii, iwulo ise iwadii

Citation

Ogbon isewadii ninu imo Eda-ede, Litireso ati Asa Yoruba

Collections