Ero bayeseri Ojogbon Alaba lori oro esin ninu Asayan Arofo

No Thumbnail Available

Date

2017

Journal Title

Journal ISSN

Volume Title

Publisher

Dept of Linguistics, African & Asian Studies, University of Lagos

Abstract

Àfojúsùn àpilẹ̀kọ yìí ni láti wo èrò báyéṣerí Ọ̀jọ̀gbọ́n Àlàbá lórí ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn nínú ọ̀kan nínú iṣẹ́ rẹ̀ tí ó pè ní Àṣàyàn Àròfọ̀ (2003). A ṣàmúlò ewì mẹ́ta tó jẹ mọ́ orí-ọ̀rọ̀ tí a yàn láàyò lára orì-ọ̀rọ̀ mẹ́ẹ̀dọ́gbọ̀n tí ó wà nínú ìwé náà pẹ̀lú lílo tíọ́rì ìlò-àmì ajẹmáwùjọ (Socio-semiotics) fún ìtúpalẹ̀. Tíọ́rì ìmọ̀ ìlò-àmì ajẹmáwùjọ tẹpẹlẹ mọ́ ọ̀gangan ipò ìṣẹ̀lẹ̀ (èyí tí í ṣe orí-ọ̀rọ̀ afọ̀, ìṣọwọ́ṣafọ̀ àti ọ̀nà ìgbàṣafọ̀) àti ọ̀gangan ipò àṣà. Kókó orí-ọ̀rọ̀ afọ̀ ni ṣíṣe ohun gbogbo ní ìwọ̀ntun-wọ̀nsì nípa ẹ̀sìn, fífi ọ̀rọ̀ ẹ̀sìn bojú ṣe ohun gbogbo ní orílẹ̀-èdè Nàìjíríà, àti àwọn ìwà àìṣedéédé lọ́wọ́ àwọn ọmọ Nàìjíríà. Ìṣọwọ́ṣàfọ̀ sọ nípa àjọṣepọ̀ tó wà láààrin akewì àti àwọn ọmọ Nàìjíríà tó kọ ewì fún. Àjọṣepọ̀ tí ọ̀kan nínú àgbàlagbà ọmọ orílẹ̀-èdè tí ọ̀rọ̀ ìṣẹ̀lẹ̀ àwùjọ rẹ̀ jẹ lógún. Ọ̀nà ìgbàṣafọ̀ akewì ni bíbu ẹnu àtẹ́ lu ìwà ìmẹ́lẹ̀ lórúkọ ẹ̀sìn nípa lílo àwọn ọnà-èdè bí i: ìfohunpènìyàn, ìfọ̀rọ̀dárà, àti àkànlò-èdè. Ìrírí akewì tí ó fi gbé ewì kalẹ̀ àti ti lámèétọ́ tí ó ṣe ìtúpalẹ̀ ewì ni ó jẹyọ ní ọ̀gangan ipò àṣà. Ìṣẹ́ yìí gúnlẹ̀ pé tí ènìyàn bá farabalẹ̀ ṣe lámèétọ́ iṣẹ́-ọnà kan dáradára pẹ̀lú tíọ́rí ìmọ̀ ìlò-àmì ajẹmáwùjọ, kò ní í ṣòro láti mọ èrò báyéṣerí oníṣẹ́-ọnà kan lóri ètò àwùjọ rẹ̀.

Description

N/A

Keywords

ero bayeseri, esin, tiori ilo-ami ajemawujo

Citation

N/A

Collections