Fagunwa ati eto oro-aje awujo Naijiria

dc.contributor.authorAdeosun, Hezekiah Olufemi
dc.date.accessioned2018-06-20T09:31:03Z
dc.date.available2018-06-20T09:31:03Z
dc.date.issued2016
dc.description.abstractÒdú ni Fágúnwà ní àwùjọ ìtàn àròsọ Yorùbá kì í ṣe àìmọ̀ fólóko. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni àwọn onímọ̀ ti ṣe lórí kókó-èrò kan tàbí òmíràn nínú àwọn ìtàn àròsọ Fágúnwà. Àmọ́ ọ̀tun-ọ̀tun lọjọ́ ń yọ lọ̀rọ̀ ìmọ̀ jẹ́, ojú tí a gbà wo ìtàn àròsọ Fágúnwà nínú iṣẹ́ yìí yàtọ̀ díẹ̀ sí èyí tí àwọn àṣáájú ti ṣe. Èròńgbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣàgbéyẹ̀wò ètò ọrọ̀-ajé àwújọ tí Fágúnwà fara mọ́ nínú àwọn ìtàn àròsọ rẹ̀. A ṣe àmúlò mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ rẹ márùn ún tó gbajú-gbajà. Àwọn ìwé náà ni Igbó Olódùmarè, Ìrèké Oníbùdó àti Àdììtú Olódùmarè. A ṣe àmúlò àwọn ìwè mẹta yìí nítorí nínú wọn ni à ti rí èrò Fágúnwà lórí ètò ọrọ-ajé àwújọ. Tíọ́rì tó tẹlé èrò Máàsì ni a fi ṣe àtẹ̀gùn fún ìṣẹ́ náà. Àbájáde iṣẹ́ yìí fi hàn pé Fágúnwá kọ ìhà tí ó ga díẹ̀ sí ètò ọrọ̀-ajé olókòwò aládàáńlá gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀-ajé àwùjọ ṣe rí ní àkókó tirẹ̀. Bí ó ṣe fi àǹfàní tó wà nínú irúfẹ ètò ọrọ̀-ajé yìí hàn náà ni ó pe àkíyèsí wa sí ewu tí ó rọ̀gbà yí i ká. Ní ìgúnlẹ̀, iṣẹ́ yìí dábàá pé ètò ọrọ̀-ajé alájọni yóò ṣe àwọn ènìyàn àwùjọ bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ànfàní, nítorí pe àjọni ni àwọn ohun ìní àwùjọ bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí ti ètò ọrọ̀-ajé olókòwò aládàáńlá (irúfẹ́ ti Nàìjíríà) tí ọrọ̀ àwújọ ń bẹ lọ́wọ́ ìwọ̀nba àwọn ènìyàn díẹ, tí wọ́n sì fi ń jẹ gàba lórí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àwùjọ.en_US
dc.description.sponsorshipYoruba Studies Association of Nigeriaen_US
dc.identifier.isbn978-34934-9-3
dc.identifier.urihttp://hdl.handle.net/123456789/596
dc.language.isootheren_US
dc.publisherYoruba studies Association of Nigeriaen_US
dc.subjectOro-aje alajonien_US
dc.subjectOro-aje alajogbe bukataen_US
dc.subjectOro-aje olokoowo aladaanlaen_US
dc.titleFagunwa ati eto oro-aje awujo Naijiriaen_US
dc.typeBook chapteren_US

Files

Original bundle
Now showing 1 - 1 of 1
No Thumbnail Available
Name:
OTUN IMO NINU ITAN-AROSO D_O.pdf
Size:
5.1 MB
Format:
Adobe Portable Document Format
Description:
main article
License bundle
Now showing 1 - 1 of 1
No Thumbnail Available
Name:
license.txt
Size:
1.69 KB
Format:
Item-specific license agreed upon to submission
Description:

Collections