Agbeyewo oriki Egba ati awon olu-ilu abe re

dc.contributor.authorAdeosun & Oyekunle, Hezekiah Olufemi & Bolanle
dc.date.accessioned2019-04-05T07:48:57Z
dc.date.available2019-04-05T07:48:57Z
dc.date.issued2018-04
dc.descriptionNILen_US
dc.description.abstractỌ̀pọ̀lọpọ̀ ni iṣẹ́ tó wà lórí oríkì, gẹ́gẹ́ bí ọ̀kan lára ewì alohùn Yorùbá, bẹ́ẹ̀ náà ni a ní oríṣiríṣri àgbàsílẹ̀ lórí oríkì àwọn èyà tí à ń pè ní Ẹ̀gbá láààrin àwọn Yorùbá. Yàtọ̀ sí àwọn rẹ́kọ́ọ̀dù láti ọwọ́ Suleiman Ayílárá (Ajóbíewé), Ọlátúbọ̀sún Ọládàpọ̀, àti àwọn mìíràn, kò tí ì sí àgbàsílẹ̀ oríkì Ẹ̀gbá àti ti àwọn olú ìlú abẹ́ rẹ̀ ní kíkún, kò sì tí ì sí iṣẹ́ ìtúpalẹ̀ kankan tó hàn sí aṣèwádìí yìí tó gùn lé tíọ́rì ìmọ̀-ìlò-àmì-ajẹmáwùjọ lórí wọn. Àìfi béè kà àwọn ewì alohùn Yorùbá sí, pàápàá oríkì, ló gún wa ní kẹ́ṣẹ́ inú fún iṣẹ́ yìí. Èròngbà iṣẹ́ yìí ni láti dí àlàfo tó wà lórí àìsí ọ̀pọ̀ iṣẹ́ lórí oríkì Ègbá àti àwọn olú-ìlú abé rè. Ọgbón ìṣèwádìí tí a mú lò ni ṣíṣe àgbàjọ ìtàn orírun àti oríkì àwọn Ẹ̀gbá ní ìjọba ìbílẹ̀ Gúúsù Abẹ́òkúta, Àríwá Abẹ́òkúta àti Ọbáfẹ́mi Owódé, níbi tí a ti lè rí àwọn olú ìlú Ẹ̀gbá mẹ́rẹ̀ẹ̀rin; Aké, Òkè-ọnà, Àgùrá àti Òwu, a sì yan abẹ́nà-ìmọ̀ márùn-ún tí ọjọ́ orí wọn wà láàárín ọgọ́ta sí ọgọ́rùn-ún ọdún. A ṣàmúlò tíọ́rì ìmọ̀-ìlò-àmì-ajẹmáwùjọfún ìtúpalẹ̀ àwọn oríkì tí a gbà. Ìmọ̀ ìlò-àmì-ajẹmáwùjọ jẹ́ ẹ̀ka lábẹ́ ìmọ̀-ìlò-àmì tó ń wádìí ìṣe ẹ̀dá tó lápẹẹrẹ nínú àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ ajẹmáwùjọ àti ajẹmáṣà, tí ó sì ń gbìyànjú láti ṣàlàyé ìfúnnítumọ̀ gẹ́gẹ́ bí ìṣe àwùjọ. Tíọ́rì yìí pín sí ọ̀nà méjì gbòógì; ọ̀gangan-ipò-ìṣẹ̀lẹ̀ àti ọ̀gangan-ipò-àṣà. Ọ̀gangan-ipò-ìṣẹ̀lẹ̀ ní tirẹ̀ ní ọmọ mẹ́ta ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ lábẹ́; orí-ọ̀rọ̀-afọ̀, ìṣọwọ́ṣafọ̀ àti ọ̀nà ìgbàṣafọ̀. Ìṣàmúlò tíọ́rì yìí ló fún iṣẹ́ àkànṣe yìí ní àǹfààní láti ṣe àfàyọ àwọn ìṣe ẹ̀dá kọ̀ọ̀kan, tí a sì tún ṣe ìfúnnítumọ̀ tòótọ́ fún àwọn ìṣẹ̀lẹ̀ inú àwọn oríkì náà. Iṣẹ́ yìí ṣe àkíyèsí pé oríkì Yorùbá jẹ́ ọ̀nà pàtàkì tí ènìyàn lè gbà tọpinpin orírun ẹnìkan, ìdílé, tàbí ìlú kan. Ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn kò ka oríkì àti àwọn ewì alohùn Yorùbá tó kù sí mọ́, pàápàá àwọn ọmọ bíbí ilẹ̀ Yorùbá gan-an. Àpilẹ̀kọ yìí dábàá kí a túbọ̀ tẹra mọ́ àgbàjọ, ṣíṣe àkọsílẹ̀ àti ìtúpalẹ̀ àwọn ewì alohùn Yorùbá, kí wọ́n má baà lọ sí òkun ìgbàgbé.en_US
dc.description.sponsorshipSelfen_US
dc.identifier.issn2141-5420
dc.identifier.urihttp://hdl.handle.net/123456789/1698
dc.language.isootheren_US
dc.publisherDept of Linguistics & Language, Adekunle Ajasin Universityen_US
dc.relation.ispartofseriesNo. 9 special edition;
dc.subjectOriki Egba,en_US
dc.subjectImo ilo-ewi ajemawujoen_US
dc.titleAgbeyewo oriki Egba ati awon olu-ilu abe reen_US
dc.typeArticleen_US

Files

Original bundle
Now showing 1 - 1 of 1
No Thumbnail Available
Name:
Akungba Jornal 2.pdf
Size:
2.14 MB
Format:
Adobe Portable Document Format
Description:
main article
License bundle
Now showing 1 - 1 of 1
No Thumbnail Available
Name:
license.txt
Size:
1.69 KB
Format:
Item-specific license agreed upon to submission
Description:

Collections