Fagunwa ati eto oro-aje awujo Naijiria

No Thumbnail Available

Date

2016

Authors

Adeosun, Hezekiah Olufemi

Journal Title

Journal ISSN

Volume Title

Publisher

Yoruba Studies Association of Nigeria

Abstract

Òdú ni Fágúnwà ní àwùjọ ìtàn àròsọ Yorùbá kì í ṣe àìmọ̀ fólóko. Ọ̀pọ̀lọpọ̀ iṣẹ́ ni àwọn onímọ̀ ti ṣe lórí kókó-èrò kan tàbí òmíràn nínú àwọn ìtàn àròsọ Fágúnwà. Àmọ́ ọ̀tun-ọ̀tun lọjọ́ ń yọ lọ̀rọ̀ ìmọ̀ jẹ́, ojú tí a gbà wo ìtàn àròsọ Fágúnwà nínú iṣẹ́ yìí yàtọ̀ díẹ̀ sí èyí tí àwọn àṣáájú ti ṣe. Èròńgbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣàgbéyẹ̀wò ètò ọrọ̀-ajé àwújọ tí Fágúnwà fara mọ́ nínú àwọn ìtàn àròsọ rẹ̀. A ṣe àmúlò mẹ́ta nínú àwọn ìwé ìtàn àròsọ rẹ márùn ún tó gbajú-gbajà. Àwọn ìwé náà ni Igbó Olódùmarè, Ìrèké Oníbùdó àti Àdììtú Olódùmarè. A ṣe àmúlò àwọn ìwè mẹta yìí nítorí nínú wọn ni à ti rí èrò Fágúnwà lórí ètò ọrọ-ajé àwújọ. Tíọ́rì tó tẹlé èrò Máàsì ni a fi ṣe àtẹ̀gùn fún ìṣẹ́ náà. Àbájáde iṣẹ́ yìí fi hàn pé Fágúnwá kọ ìhà tí ó ga díẹ̀ sí ètò ọrọ̀-ajé olókòwò aládàáńlá gẹ́gẹ́ bí ètò ọrọ̀-ajé àwùjọ ṣe rí ní àkókó tirẹ̀. Bí ó ṣe fi àǹfàní tó wà nínú irúfẹ ètò ọrọ̀-ajé yìí hàn náà ni ó pe àkíyèsí wa sí ewu tí ó rọ̀gbà yí i ká. Ní ìgúnlẹ̀, iṣẹ́ yìí dábàá pé ètò ọrọ̀-ajé alájọni yóò ṣe àwọn ènìyàn àwùjọ bí orílẹ̀-èdè Nàìjíríà ní ànfàní, nítorí pe àjọni ni àwọn ohun ìní àwùjọ bẹ́ẹ̀, yàtọ̀ sí ti ètò ọrọ̀-ajé olókòwò aládàáńlá (irúfẹ́ ti Nàìjíríà) tí ọrọ̀ àwújọ ń bẹ lọ́wọ́ ìwọ̀nba àwọn ènìyàn díẹ, tí wọ́n sì fi ń jẹ gàba lórí ọ̀pọ̀ ènìyàn ní àwùjọ.

Description

NIL

Keywords

Fagunwa, Eto oro-aje, Itan aroso

Citation

NIL

Collections