Akitiyan Bade Ajayi lori isatunpin ihun ese Ifa

No Thumbnail Available

Date

2014

Journal Title

Journal ISSN

Volume Title

Publisher

Dept of Linguistics & Nigerian Languages, UNILORIN

Abstract

Ifá jẹ́ àkójọpọ̀ ọgbọ́n àti ìrírí àwọn Yorùbá. Oríṣiríṣi nǹkan nípa èrò ọkàn àti ìtàn àwọn Yorùbá ló sì pé sínú rẹ. Ẹsẹ Ifá ni àwọn ìtàn tí à ń bá pàdé nínú Ifá. Èròńgbà iṣẹ́ yìí ni láti ṣe àgbéyẹwò ìṣàtúnpín ìhun ẹsẹ Ifá tí Àjàyí (2002) ṣe nínú iṣẹ́ rè tí ó pè ní Ifá Divination: Its practice among the Yorùbá of Nigeria. Kí èròńgbà iṣẹ́ yìí tó wá sí ìmúṣẹ, a wo àwọn àkọsílẹ̀ tí ó tí wà ṣáájú ti Àjàyí (2002) lórí ìhun ẹsẹ Ifá, kí á tó wo bí Àjàyí ṣe pín tirè. Àbájáde iṣẹ́ yìí fihàn pé àwọn onímọ̀ mẹ́rin ọ̀tọ̀ọ̀tọ̀ ni wọ́n ti ṣiṣẹ́ takuntakun lórí ìpín ìhun ẹsẹ Ifá àti ìlànà tí wọ́n gbà fi pín in. Àwọn onímọ̀ náà ni Raymond (1964), Bascom (1969), Abímbọ́lá (1976) àti Ọlátúnjí (1984). Iṣẹ́ yìí gúnlẹ̀ pẹ̀lú àlàkalẹ̀ ọ̀nà mẹ́ta gbòòrò tí Bádé Àjàyí ní a lè gbà láti pín ìhun ẹsẹ Ifá. Àwọn ọ̀nà mẹ́ta náà ni ọ̀rọ̀ àkọ́sọ, ìtàn Ifá, àti ọ̀rọ̀ àsọkágbá. Ní èrò tiwa, ìlànà ọ̀tun yìí rọrùn díẹ̀ ju ti àtẹ̀hìnwà lọ láti pín ìhun ẹsẹ Ifá.

Description

NIL

Keywords

ihun ese ifa, tiori ifoju ihun ajemawujo wo

Citation

Collections