Ete ifiwaweda ninu iwe ere-onitan Ori mekunnu ati eto isejoba orile-ede Naijiria

No Thumbnail Available

Date

2014

Journal Title

Journal ISSN

Volume Title

Publisher

Dept of Linguistics, African & Asian Studies, University of Lagos

Abstract

Ìṣòro tí o kojú àwùjọ, pàápàá àwọn mêkúnnù, nípa ìwà ìbàjẹ àti ìwà ìrënijẹ-rẹnipa nígbà mìíràn nínú ètò ìṣèlú ilê Nàìjíríà àti ọpọ ilẹ adúláwô mìíràn gẹgẹ bí ó ṣe jẹyọ nínú ìwé eré-onítàn, Orí Mêkúnnù ni ó jẹ isẹ yìí lógún. Àwọn ìwà àìtọ àti tí “bàbá ta ni yóó mú mi” tí àwọn onípò àti olórí n hù sí mêkúnnù jẹ ohun tí ó ba ònkôwé yìí nínú jẹ tí ó sì mú un lọkàn gidigidi. Tíọrì tó têlé èrò Máàsì ni a ṣàmúlò nínú iṣẹ yìí. A ṣe àmúlò tíọrì yìí nítorí ó jẹ tíọrì tí ó ṣe àfihàn àwön ẹlẹgbëjẹgbë inú àwùjọ kan, ètò ìṣèlú, ọrô-ajé àti ìbára-ẹni-gbé-pô àwọn ènìyàn àwùjọ bëê látàrí àtiwá ọnà àbáyọ sí ìṣòro wọn. Díê nínú àbájáde ìwádìí yìí ni pé òṣèré/ẹdá ìtàn kôôkan nínú ìwé-eré-onítàn tí a yêwò yìí dúró fún orísìí ènìyàn àwùjö nínú ìṣèlú Yorùbá àti Nàìjíríà lápapô. Lára irúfë ènìyàn bëê ni Adékànmbí tí ó mọ pé àwön ará ìlú ò fë òun ṣùgbọn tí ó pín rìbá fún mẹta nínú àwọn afọbajẹ kí ó lè dé orí oyè ní túlàasì. Ó dé orí oyè lótìítọ ṣùgbọn kò pẹ níbẹ tí ó fi kú ikú ẹsín. Irú àwön afipá-ṣèlú bi Adékànmbí kún àárín àwön olóṣèlú wá lónìí tí wön ò jë kí ará ìlú yan ẹni tí ôkan wön fë sípò, bẹẹ bí wõn débê tán, ìnira ni wọn n kó bá mêkúnnù. Irú àwọn ènìyàn báyìí ni kò jë kí orílê-èdè Nàìjíríà dàgbà ju bí ó ṣe wà yìí. Bí tolórí-tẹlẹmù àwùjọ bá ní ẹrí ọkàn rere tí wọn sì n bọwọ fún òfin ìyannisípò àti ìdìbò, irú àwön ènìyàn wọnyí kò ní rí ônà lọ mọ nínú ètò ìṣèlú àwùjọ. Nípa báyìí, a ó máa ní àwọn olórí tí ó dára gẹgẹ bí aṣíwájú nínú ìṣèlú. Ìjìyà tí ó nípọn yẹ kí ó tún wà fún àwön tí ó bá rú òfin ìyannisípò àti ti ìdìbò nínú òfin orílê-èdè wa kí ó lè jẹ kí àwọn aṣebi nínú ìṣèlú bẹrù.

Description

N/A

Keywords

tiori Maasi, ete ifiwaweda

Citation

N/A

Collections