Okewande, Oluwole Tewogboye2021-02-032021-02-0320180794-4551http://hdl.handle.net/123456789/4261Àmúlò oríṣìíríṣìí àwọn àbùdá ajẹmédè pè fún ìkẹ́sẹjárí, ìpegedé àti ìjágaara àmújáde ìtumọ̀ afọ̀ fún onímọ̀-èdè, nínú ìmọ̀ ìmédèlò. Ṣaájú àkókò yìí, kò tí ì sí iṣẹ́ ìwádìí kan gúnmọ́ lórí àtẹ tó ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí àwọn ìlànà ìṣowọ́lò-èdè ìṣọfọ̀ wọ̀nyìí ń kó láwùjọ Yorùbá. À̀làfo yìí niṣẹ́ ìwádìí yìí yóò dí. Nipasẹ̀ èyí, àtubọ̀tán iṣẹ́ yìí ni láti ṣàgbéyẹ̀wò ipa tí ìlò ohùn àti ìró ẹ̀ka-èdè àti èdè àmúlò ń kó nínú ìmèdè bí atọ́ka ìṣọwọ́ afọ̀ fún ìkẹ́sẹjárí-ìlò-èdè àti àgbọ́yé-afọ̀ láwùjọ Yorùbá. Iṣẹ́ yìí ṣàmúlò èdè fáyẹ̀wò láti ara ìsọ̀rí ọfọ̀ látinú oríṣìí afọ̀. Ìtúpalẹ̀ àkójọ-èdè-fáyẹ̀wò inú iṣẹ́ yìí fìdí rẹ̀ múlẹ̀ pé, ipa tí ìmọ̀ nípa ìlò ohùn àti ìró, èdè-àmúlò àti ẹ̀ka-èdè, bí atọ́ka ìṣọwọ́ afọ̀ ń kó nínú ìmèdè, ìkẹ́sẹjárí-ìlò-èdè, àgbọ́yé-afọ̀ àti ìtumọ̀ kò ṣe é fojú tín-ín-rín rárá. Èyí ni pé, láìsí ìpegedé àti ìjáfáfá aṣafọ̀ nínú ìṣafọ̀ àmúlò àwọn fọ́nrán-èdè fáyẹ̀wò tíṣẹ́ yìí fi ṣàtẹ̀gùn ìtúpalẹ̀, àìgbọ́ra-ẹni-yé, ìtumọ̀-òdì tàbí ìyítumọ̀po ni yóò wáyé nínú ìṣọfọ̀.enÌṣọwọ́lò-èdèÌṣọwọ́Ìró àti ohùnÈdè-àmúlòẸ̀ka-èdèỌfọ̀Isowolo-Ede Ofo ninu Asayan Oro ati Afo YorubaArticle